Sefaniah 1:4
Zephaniah 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,
Zephaniah 1:4 in English
Zephaniah 1:4 · Berean Standard Bible
“I will stretch out My hand against Judah and against all who dwell in Jerusalem. I will cut off from this place every remnant of Baal, the names of the idolatrous and pagan priests—
Context
2“Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò
lórí ilẹ̀ náà pátápátá,”
ni Olúwa wí. 3“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò;
èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò, àti ẹja inú Òkun,
àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú;
èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”
ni Olúwa wí. 4“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda
àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.
Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà
pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, 5àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé,
àwọn tí ń sin ogun ọ̀run,
àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,
tí wọ́n sì ń fi Moleki búra. 6Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;
àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.