Sekariah 9:6
Zechariah 9:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu, Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.
Zechariah 9:6 in English
Zechariah 9:6 · Berean Standard Bible
A mixed race will occupy Ashdod, and I will cut off the pride of the Philistines.
Context
4Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,
yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun,
a ó sì fi iná jó o run. 5Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;
Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi,
àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í.
Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀,
Aṣkeloni yóò sì di ahoro. 6Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu,
Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò. 7Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,
àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀:
ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,
wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda,
àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi. 8Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká
nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri,
kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́:
nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.