Native Bible

Zechariah 9:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run.

Zechariah 9:4 in English

Zechariah 9:4 · Berean Standard Bible

Behold, the Lord will impoverish her and cast her wealth into the sea,* and she will be consumed by fire.

Context

2Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi. 3Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro. 4Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run. 5Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi, àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í. Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro. 6Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu, Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.