Sekariah 9:3
Zechariah 9:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro.
Zechariah 9:3 in English
Zechariah 9:3 · Berean Standard Bible
Tyre has built herself a fortress; she has heaped up silver like dust, and gold like the dirt of the streets.
Context
1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hadiraki,
Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀;
nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn,
àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli. 2Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀
Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi. 3Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀,
ó sì kó fàdákà jọ bí eruku,
àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro. 4Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,
yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun,
a ó sì fi iná jó o run. 5Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;
Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi,
àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í.
Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀,
Aṣkeloni yóò sì di ahoro.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.