Native Bible

Zechariah 8:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

Zechariah 8:18 in English

Zechariah 8:18 · Berean Standard Bible

Then the word of the LORD of Hosts came to me, saying,

Context

16Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí. 18Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé. 19Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.” 20Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.