Native Bible

Zechariah 8:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín.

Zechariah 8:16 in English

Zechariah 8:16 · Berean Standard Bible

These are the things you must do: Speak truth to one another, render true and sound judgments in your gates,

Context

14Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15“Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 16Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí. 18Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.