Sekariah 8:19
Zechariah 8:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”
Zechariah 8:19 in English
Zechariah 8:19 · Berean Standard Bible
“This is what the LORD of Hosts says: The fasts of the fourth, the fifth, the seventh, and the tenth months will become times of joy and gladness, cheerful feasts for the house of Judah. Therefore you are to love both truth and peace.”
Context
17Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí. 18Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé. 19Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.” 20Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.