Sekariah 11:3
Zechariah 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn; ògo wọn bàjẹ́; gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jordani bàjẹ́.
Zechariah 11:3 in English
Zechariah 11:3 · Berean Standard Bible
Listen to the wailing of the shepherds, for their glory is in ruins. Listen to the roaring of the young lions, for the thickets of the Jordan are destroyed.
Context
1Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni,
kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run. 2Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú,
nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:
hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani,
nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀. 3Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;
ògo wọn bàjẹ́;
gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún
nítorí ògo Jordani bàjẹ́. 4Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. 5Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.