Sekariah 11:4
Zechariah 11:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa.
Zechariah 11:4 in English
Zechariah 11:4 · Berean Standard Bible
This is what the LORD my God says: “Pasture the flock marked for slaughter,
Context
2Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú,
nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:
hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani,
nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀. 3Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;
ògo wọn bàjẹ́;
gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún
nítorí ògo Jordani bàjẹ́. 4Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. 5Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. 6Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni Olúwa wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.