Native Bible

Song of Songs 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.

Song of Songs 8:7 in English

Song of Songs 8:7 · Berean Standard Bible

Mighty waters cannot quench love; rivers cannot sweep it away. If a man were to give all the wealth of his house for love, his offer would be utterly scorned.

Context

5Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀. 6(5) Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí. (6) Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa. 7Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá. 8Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ? 9Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.