Orin Solomoni 8:5
Song of Songs 8:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀.
Song of Songs 8:5 in English
Song of Songs 8:5 · Berean Standard Bible
Who is this coming up from the wilderness, leaning on her beloved?
Context
3Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra. 4Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà.
Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè.
Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú. 5Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù,
tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀. 6(5) Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ
níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.
(6) Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì
bí èdìdì lé apá rẹ;
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,
ìjowú sì le bí isà òkú
jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa. 7Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;
bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,
ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,
a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.