Orin Solomoni 8:9
Song of Songs 8:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.
Song of Songs 8:9 in English
Song of Songs 8:9 · Berean Standard Bible
If she is a wall, we will build a tower of silver to protect her. If she is a door, we will enclose her with panels of cedar.
Context
7Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;
bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,
ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,
a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá. 8Àwa ní arábìnrin kékeré kan,
òun kò sì ní ọmú,
kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,
ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ? 9Bí òun bá jẹ́ ògiri,
àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.
Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn,
àwa yóò fi pákó kedari dí i. 10Èmi jẹ́ ògiri,
ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́
bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀
bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá. 11Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni
ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú
olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá
ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.