Native Bible

Romans 15:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Romans 15:13 in English

Romans 15:13 · Berean Standard Bible

Now may the God of hope fill you with all joy and peace as you believe in Him, so that you may overflow with hope by the power of the Holy Spirit.

Context

11Àti pẹ̀lú, “Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí; ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.” 12Isaiah sì tún wí pé, “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí; Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.” 13Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. 14Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. 15Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.