Romu 15:14
Romans 15:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín.
Romans 15:14 in English
Romans 15:14 · Berean Standard Bible
I myself am convinced, my brothers, that you yourselves are full of goodness, brimming with knowledge, and able to instruct one another.
Context
12Isaiah sì tún wí pé,
“Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá,
òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí;
Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.” 13Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. 14Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. 15Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run 16láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.