Romu 15:16
Romans 15:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́.
Romans 15:16 in English
Romans 15:16 · Berean Standard Bible
to be a minister of Christ Jesus to the Gentiles in the priestly service of the gospel of God, so that the Gentiles might become an offering acceptable to God, sanctified by the Holy Spirit.
Context
14Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. 15Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run 16láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́. 17Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. 18Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.