Romu 15:18
Romans 15:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi,
Romans 15:18 in English
Romans 15:18 · Berean Standard Bible
I will not presume to speak of anything except what Christ has accomplished through me in leading the Gentiles to obedience by word and deed,
Context
16láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìyìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ yà sí mímọ́. 17Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. 18Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi, 19nípa agbára iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìyìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 20Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.