Romu 15:12
Romans 15:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Isaiah sì tún wí pé, “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí; Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”
Romans 15:12 in English
Romans 15:12 · Berean Standard Bible
And once more, Isaiah says: “The Root of Jesse will appear, One who will arise to rule over the Gentiles; in Him the Gentiles will put their hope.”*
Context
10Ó sì tún wí pé,
“Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” 11Àti pẹ̀lú,
“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí;
ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.” 12Isaiah sì tún wí pé,
“Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá,
òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí;
Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.” 13Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. 14Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.