Native Bible

Romans 15:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti pẹ̀lú, “Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí; ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”

Romans 15:11 in English

Romans 15:11 · Berean Standard Bible

And again: “Praise the Lord, all you Gentiles, and extol Him, all you peoples.”*

Context

9kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.” 10Ó sì tún wí pé, “Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” 11Àti pẹ̀lú, “Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí; ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.” 12Isaiah sì tún wí pé, “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí; Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.” 13Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.