Romu 15:9
Romans 15:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí, Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”
Romans 15:9 in English
Romans 15:9 · Berean Standard Bible
so that the Gentiles may glorify God for His mercy. As it is written: “Therefore I will praise You among the Gentiles; I will sing hymns to Your name.”*
Context
7Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. 8Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, 9kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí,
Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.” 10Ó sì tún wí pé,
“Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” 11Àti pẹ̀lú,
“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí;
ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.