Ìfihàn 19:7
Revelation 19:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un. Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán.
Revelation 19:7 in English
Revelation 19:7 · Berean Standard Bible
Let us rejoice and be glad and give Him the glory. For the marriage of the Lamb has come, and His bride has made herself ready.
Context
5Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:
“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti èwe àti àgbà!” 6Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé:
“Haleluya!
Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba. 7Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,
kí a sì fi ògo fún un.
Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,
aya rẹ̀ sì ti múra tán. 8Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀
wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”
(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.) 9Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.