Native Bible

Revelation 19:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.” (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

Revelation 19:8 in English

Revelation 19:8 · Berean Standard Bible

She was given clothing of fine linen, bright and pure.” For the fine linen she wears is the righteous acts of the saints.

Context

6Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba. 7Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un. Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán. 8Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.” (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.) 9Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.” 10Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.