Native Bible

Revelation 19:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.

Revelation 19:6 in English

Revelation 19:6 · Berean Standard Bible

And I heard a sound like the roar of a great multitude, like the rushing of many waters, and like a mighty rumbling of thunder, crying out: “Hallelujah! For the Lord our God * the Almighty reigns.

Context

4Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé: “Àmín, Haleluya!” 5Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti èwe àti àgbà!” 6Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńlá ńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba. 7Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un. Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé, aya rẹ̀ sì ti múra tán. 8Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.” (Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.