Ìfihàn 18:21
Revelation 18:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé: “Báyìí ní a ó fi agbára ńlá bí i Babeli ìlú ńlá ni wó, a kì yóò sì rí i mọ́ láé.
Revelation 18:21 in English
Revelation 18:21 · Berean Standard Bible
Then a mighty angel picked up a stone the size of a great millstone and cast it into the sea, saying: “With such violence the great city of Babylon will be cast down, never to be seen again.
Context
19Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀
ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!
Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’ 20“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!
Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀
nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.” 21Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé:
“Báyìí ní a ó fi agbára ńlá
bí i Babeli ìlú ńlá ni wó,
a kì yóò sì rí i mọ́ láé. 22Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,
àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè,
ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;
àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé.
Àti ìró ọlọ ní a kì yóò
sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé; 23Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé;
a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé:
nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé;
nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.