Ìfihàn 18:19
Revelation 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’
Revelation 18:19 in English
Revelation 18:19 · Berean Standard Bible
Then they will throw dust on their heads as they weep and mourn and cry out: “Woe, woe to the great city, where all who had ships on the sea were enriched by her wealth! For in a single hour she has been destroyed.”
Context
17Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’
“Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, 18wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ 19Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀
ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!
Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’ 20“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!
Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀
nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.” 21Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé:
“Báyìí ní a ó fi agbára ńlá
bí i Babeli ìlú ńlá ni wó,
a kì yóò sì rí i mọ́ láé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.