Ìfihàn 18:17
Revelation 18:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré,
Revelation 18:17 in English
Revelation 18:17 · Berean Standard Bible
For in a single hour such fabulous wealth has been destroyed!” Every shipmaster, passenger, and sailor, and all who make their living from the sea, will stand at a distance
Context
15Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, 16wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì,
tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,
àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali! 17Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’
“Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, 18wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ 19Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀
ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!
Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.