Ìfihàn 18:15
Revelation 18:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀,
Revelation 18:15 in English
Revelation 18:15 · Berean Standard Bible
The merchants who sold these things and grew their wealth from her will stand at a distance, in fear of her torment. They will weep and mourn,
Context
13Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn. 14“Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé. 15Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, 16wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì,
tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,
àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali! 17Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’
“Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.