Ìfihàn 18:20
Revelation 18:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”
Revelation 18:20 in English
Revelation 18:20 · Berean Standard Bible
Rejoice over her, O heaven, O saints and apostles and prophets, because God has pronounced for you His judgment against her.
Context
18wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ 19Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀
ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!
Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’ 20“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!
Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀
nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.” 21Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé:
“Báyìí ní a ó fi agbára ńlá
bí i Babeli ìlú ńlá ni wó,
a kì yóò sì rí i mọ́ láé. 22Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,
àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè,
ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;
àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé.
Àti ìró ọlọ ní a kì yóò
sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.