Ìfihàn 18:23
Revelation 18:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé; a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé: nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé; nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ.
Revelation 18:23 in English
Revelation 18:23 · Berean Standard Bible
The light of a lamp will never shine in you again, and the voices of a bride and bridegroom will never call out in you again. For your merchants were the great ones of the earth, because all the nations were deceived by your sorcery.”
Context
21Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé:
“Báyìí ní a ó fi agbára ńlá
bí i Babeli ìlú ńlá ni wó,
a kì yóò sì rí i mọ́ láé. 22Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,
àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè,
ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;
àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé.
Àti ìró ọlọ ní a kì yóò
sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé; 23Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé;
a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé:
nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé;
nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ. 24Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì,
àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.