Native Bible

Psalms 92:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

Psalms 92:8 in English

Psalms 92:8 · Berean Standard Bible

But You, O LORD, are exalted forever!

Context

6Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n, aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n, 7nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé. 8Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé. 9Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká. 10Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.