Saamu 92:7
Psalms 92:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé.
Psalms 92:7 in English
Psalms 92:7 · Berean Standard Bible
that though the wicked sprout like grass, and all evildoers flourish, they will be forever destroyed.
Context
5Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni! 6Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n, 7nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé. 8Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé. 9Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
ni a ó fọ́nká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.