Saamu 88:4
Psalms 88:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀ èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
Psalms 88:4 in English
Psalms 88:4 · Berean Standard Bible
I am counted among those descending to the Pit. I am like a man without strength.
Context
2Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
dẹ etí rẹ sí igbe mi. 3Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú. 4A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára. 5A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú. 6Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.