Native Bible

Psalms 88:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.

Psalms 88:3 in English

Psalms 88:3 · Berean Standard Bible

For my soul is full of troubles, and my life draws near to Sheol.

Context

1Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là, ní ọ̀sán àti ní òru, mo kígbe sókè sí Ọ. 2Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ; dẹ etí rẹ sí igbe mi. 3Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú. 4A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀ èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára. 5A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.