Native Bible

Psalms 86:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè.

Psalms 86:14 in English

Psalms 86:14 · Berean Standard Bible

The arrogant rise against me, O God; a band of ruthless men seeks my life, with no regard for You.

Context

12Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé. 13Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. 14Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè. 15Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́. 16Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.