Native Bible

Psalms 86:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.

Psalms 86:12 in English

Psalms 86:12 · Berean Standard Bible

I will praise You, O Lord my God, with all my heart; I will glorify Your name forever.

Context

10Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run. 11Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ. 12Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé. 13Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. 14Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.