Native Bible

Psalms 78:57 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà, wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.

Psalms 78:57 in English

Psalms 78:57 · Berean Standard Bible

They turned back and were faithless like their fathers, twisted like a faulty bow.

Context

55Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn. 56Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo; wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. 57Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà, wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn. 58Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn. 59Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ Israẹli pátápátá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.