Native Bible

Psalms 78:55 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.

Psalms 78:55 in English

Psalms 78:55 · Berean Standard Bible

He drove out nations before them and apportioned their inheritance; He settled the tribes of Israel in their tents.

Context

53Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn. 54Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà 55Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn. 56Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo; wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. 57Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà, wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.