Saamu 73:3
Psalms 73:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.
Psalms 73:3 in English
Psalms 73:3 · Berean Standard Bible
For I envied the arrogant when I saw the prosperity of the wicked.
Context
1Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
fún àwọn ọlọ́kàn funfun. 2Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán. 3Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú. 4Wọn kò ṣe wàhálà;
ara wọn mókun wọn sì lágbára. 5Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.