Native Bible

Psalms 72:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò sì pẹ́ ní ayé! A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba. Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́.

Psalms 72:15 in English

Psalms 72:15 · Berean Standard Bible

Long may he live! May gold from Sheba be given him. May people ever pray for him; may they bless him all day long.

Context

13Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú. 14Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀. 15Yóò sì pẹ́ ní ayé! A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba. Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́. 16Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀; ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀. 17Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé; orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó. Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.