Native Bible

Psalms 72:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀.

Psalms 72:14 in English

Psalms 72:14 · Berean Standard Bible

He will redeem them from oppression and violence, for their blood is precious in his sight.

Context

12Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. 13Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú. 14Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀. 15Yóò sì pẹ́ ní ayé! A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba. Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́. 16Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀; ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.