Native Bible

Psalms 6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Listen to Saamu 6
1Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ. 2Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira. 3Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó? 4Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í. 5Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú? 6Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé. 7Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi. 8Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi. 9Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi. 10Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.