Saamu 6:3
Psalms 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
Psalms 6:3 in English
Psalms 6:3 · Berean Standard Bible
My soul is deeply distressed. How long, O LORD, how long?
Context
1Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ. 2Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira. 3Ọkàn mi wà nínú ìrora.
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó? 4Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í. 5Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.