Saamu 45:10
Psalms 45:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.
Psalms 45:10 in English
Psalms 45:10 · Berean Standard Bible
Listen, O daughter! Consider and incline your ear: Forget your people and your father’s house,
Context
8Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn. 9Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà Ofiri. 10Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ. 11Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un. 12Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.