Native Bible

Psalms 45:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.

Psalms 45:8 in English

Psalms 45:8 · Berean Standard Bible

All your garments are fragrant with myrrh and aloes and cassia; from palaces of ivory the harps make you glad.

Context

6Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni. 7Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́. 8Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn. 9Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà Ofiri. 10Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.