Saamu 45:6
Psalms 45:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
Psalms 45:6 in English
Psalms 45:6 · Berean Standard Bible
Your throne, O God, endures forever and ever, and justice is the scepter of Your kingdom.
Context
4Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́,
ìwà tútù àti òtítọ́;
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù. 5Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 6Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni. 7Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́. 8Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.