Native Bible

Psalms 45:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

Psalms 45:5 in English

Psalms 45:5 · Berean Standard Bible

Your arrows pierce the hearts of the king’s foes; the nations fall beneath your feet.

Context

3Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá. 4Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́; jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù. 5Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 6Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni. 7Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.