Native Bible

Psalms 44:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.

Psalms 44:4 in English

Psalms 44:4 · Berean Standard Bible

You are my King, O God, who ordains victories for Jacob.

Context

2Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde, Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀. 3Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn. 4Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu. 5Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀, 6èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi, idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.