Native Bible

Psalms 44:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

Psalms 44:3 in English

Psalms 44:3 · Berean Standard Bible

For it was not by their sword that they took the land; their arm did not bring them victory. It was by Your right hand, Your arm, and the light of Your face, because You favored them.

Context

1À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run; àwọn baba wa tí sọ fún wa ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn. 2Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde, Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀. 3Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn. 4Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu. 5Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.