Saamu 40:6
Psalms 40:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè.
Psalms 40:6 in English
Psalms 40:6 · Berean Standard Bible
Sacrifice and offering You did not desire, but my ears You have opened.* Burnt offerings and sin offerings You did not require.
Context
4Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn. 5Olúwa Ọlọ́run mi,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ,
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ. 6Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
ni ìwọ kò béèrè. 7Nígbà náà ni mo wí pé,
“Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
a kọ ọ nípa tèmi wí pé. 8Mo ní inú dídùn
láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi,
òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.