Native Bible

Psalms 40:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé.

Psalms 40:7 in English

Psalms 40:7 · Berean Standard Bible

Then I said, “Here I am, I have come— it is written about me in the scroll:

Context

5Olúwa Ọlọ́run mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe. Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa; ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ, tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọ́n ju ohun tí ènìyàn le è kà lọ. 6Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè. 7Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé. 8Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.” 9Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrín àwùjọ ńlá; wò ó, èmi kò pa ètè mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.