Native Bible

Psalms 40:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ Olúwa, láti gbà mí là; Olúwa, yára láti ràn mí lọ́wọ́.

Psalms 40:13 in English

Psalms 40:13 · Berean Standard Bible

Be pleased, O LORD, to deliver me; hurry, O LORD, to help me.

Context

11Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé. 12Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà. 13Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ Olúwa, láti gbà mí là; Olúwa, yára láti ràn mí lọ́wọ́. 14Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú; àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n, àwọn tí ń wá ìpalára mi. 15Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!” ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.